James Clerk Maxwell

James Clerk Maxwell (13 June 1831 – 5 November 1879) je onimo fisiyiki oniriro ati mathematiiki ara Skotlandi. Aseyori re to se pataki ju ni iro oninagberigberin, to sakojopo gbogbo awon akiyesi, adanwo ati awon isodogba fun itanna, isegberigberin ati optiyiki teletele ti won ko baratan si iru tobaramu. Awon akojopo isodogba re—awon isodogba Maxwell—fihan pe itanna, isegberingberin ati imole na je ifarahanjade isele kanna: papa oninagberingberin. Lati igba yi siwaju, gbogbo awon ofin ati isodogba awon eka wonyi di iru mimuyanju awon isodogba Maxwell. Ise Maxwell ninu isoninagberingberin ti je pipe ni "isodokan tolokiki keji ninu fisiyiki", leyin ekinni ti Isaac Newton se. Maxwell fihan pe papa onina ati gberingberin n gba inu aaye koja gege bi oniriru, ati pelu isare imole ti ko yi pada. Nipari, ni odun 1864 Maxwell ko iwe "A dynamical theory of the electromagnetic field", ninu ibi ti o ti koko damoran pe ni ooto imole je irusilesoke ninu ohun kanna to n fa isele onina ati gberingberin. Maxwell tun seda ipinka Maxwell, ona statistiki lati sapejuwe awon ese iro imurin awon efuufu. Awon iwari mejeji yi lo mu igba fisiyiki odeoni waye, o se ifilele ise ojo iwaju ninu papa bi ijebaratan pataki ati isise ero atasere. Maxwell na lo tun da foto alawo akoko ni 1861, o si tun se ipilese idimule opo ati isopo won bi won se je mimulo ninu awon afara. Opolopo awon onimo fisiyiki gba Maxwell pe o je onimo sayensi igba orundun 19 to ni ipa pataki julo lori fisiyiki igba orundun 20. Awon afikun re si sayensi je iru kanna bi ti awon Isaac Newton ati Albert Einstein. Ninu iwadi igboro fun egberun odun, iwadi lowo awon onimo fisiyiki pataki julo dibo fun Maxwell gege bi onimo fisiyiki eketa tolokiki julo ni gbogbo igba, leyin Newton ati Einstein nikan. Ni asiko ojoibi odun ogorun Maxwell, Einstein fun ra re juwe ise Maxwell gege bi "eyi to se gbangba julo ati to wulo julo ti fisiyiki ni iriri lati igba Newton." Einstein fi foto Maxwell si ara ogiri yara ikawe re, pelu foto Michael Faraday ati Newton.


From Wikipedia, the free encyclopedia · View on Wikipedia

Developed by Tubidy